Menu

Saamu 114

BIB

1 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti, ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè

2 Juda wà ní ibi mímọ́, Israẹli wà ní ìjọba.

3 Òkun sì rí i, ó sì wárìrì: Jordani sì padà sẹ́yìn.

4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn.

5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì? Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?

6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò, àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn?

7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa; ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu

8 tí ó sọ àpáta di adágún omi, àti òkúta-ìbọn di orísun omi.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate