Saamu 136
BIB1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
4 Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
5 Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
6 Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
7 Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
8 Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
9 Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
10 Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
11 Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
13 Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀ nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkí nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
19 Sihoni, ọba àwọn ará Amori nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
20 Àti Ogu, ọba Baṣani; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
