Menu

Saamu 14

BIB

1 Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé, “Ko sí Ọlọ́run.” Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú; kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.

2 Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹni tí òye yé, ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.

3 Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́; kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.

4 Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀? Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun; wọn kò sì ké pe Olúwa?

5 Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù, nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.

6 Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú, ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.

7 Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá! Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate