Menu

Saamu 52

BIB

1 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin? Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo, ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?

2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun; ó dàbí abẹ mímú, ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.

3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ, àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.

4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé, yóò sì dì ọ́ mú, yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ, yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.

6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,

7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀, bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé, ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”

8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run; èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà láé àti láéláé.

9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe; èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ, nítorí orúkọ rẹ dára. Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate