Menu

Saamu 58

BIB

1 Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́ ẹ̀yin ìjọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́ ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?

2 Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo, ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.

3 Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà, lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.

4 Oró wọn dàbí oró ejò, wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,

5 tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú, bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.

6 Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run; ní ẹnu wọn, ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.

7 Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ; nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.

8 Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.

9 Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún; bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.

10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn, nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.

11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé, “Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo; lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate