Menu

Saamu 67

BIB

1 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa, kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,

2 kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé, ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!

4 Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀, nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn, ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.

5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.

6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run, Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.

7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate