Menu

Saamu 75

BIB

1 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run, a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí; àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.

2 Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀; Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.

3 Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì, Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.

4 Èmí wí fún àwọn agbéraga pé, ẹ má ṣe gbéraga mọ́; àti sí ènìyàn búburú; ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.

5 Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run; ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”

6 Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá tàbí ní ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.

7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́; Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.

8 Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.

9 Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé; èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.

10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate