Menu

Saamu 110

BIB

1 Olúwa sọ fún Olúwa mi pé, “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

2 Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀ láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.

3 Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́, láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.

4 Olúwa ti búra, kò sì í yí ọkàn padà pé, “Ìwọ ni àlùfáà, ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

5 Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀.

6 Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí, yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara; yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.

7 Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà: nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate