Menu

Saamu 111

BIB

1 Ẹ máa yin Olúwa. Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

2 Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.

3 Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo: àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.

4 Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí: Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.

5 Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀: òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.

6 Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀ láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní.

7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.

8 Wọ́n dúró láé àti láé, ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.

9 Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀: ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé, mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.

10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n: òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀, ìyìn rẹ̀ dúró láé.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate