Menu

Saamu 120

BIB

1 Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi, ó sì dá mi lóhùn.

2 Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.

3 Kí ni kí a fi fún ọ? Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?

4 Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun, pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.

5 Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!

6 Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.

7 Ènìyàn àlàáfíà ni mí; ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate