Menu

Saamu 121

BIB

1 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì— níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?

2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá, ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀; ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.

4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́, kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ; Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

7 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo yóò pa ọkàn rẹ mọ́

8 Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́ láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Everything we make is available for free because of a generous community of supporters.

Donate